Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí pé, “Wò ó, egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa ń ṣe.

2. Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù fi jọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Ísírẹ́lì jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ ó ṣe olùsọ́ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi, ìwọ ó sì jẹ́ olórí fún Ísírẹ́lì.’ ”

3. Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì.

4. Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba; ó sì jọba ní ogójì ọdún.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 5