Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 3:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ábínérì sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣibósẹ́tì sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Júdà bí? Di òní yìí ni mọ ṣàáánú fún ìdílé Ṣọ́ọ̀lù bàbá rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lóní?

9. Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Ábínérì, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dáfídì, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un.

10. Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, àti láti gbé ìtẹ́ Dáfídì kalẹ̀ lorí Ísírẹ́lì, àti lórí Júdà, láti Dánì títí ó fi dé Bíáṣébà!”

11. Òun kò sì lè dá Ábínérì lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12. Ábínérì sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dáfídì nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Ísírẹ́lì tọ̀ ọ́ wá.”

13. Òun sì wí pé, “Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”

14. Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ sí Iṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù pé, “Fi Míkálì obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rún atoro àwọn Fílístínì fẹ́.”

15. Íṣíbóṣétì sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Fálítíélì ọmọ Láíṣì.

16. Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sunkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Báhúrímù Ábínérì sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.

17. Ábínérì sì bá àwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dáfídì ní ìgbà àtijọ́, láti jọba lórí yín.

18. Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì pé, ‘Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn.’ ”

19. Ábínérì sì sọ̀rọ̀ létí Béńjámẹ́nì: Ábínérì sì lọ sọ létí Dáfídì ní Hébírónì, gbogbo èyí tí ó dára lójú Ísírẹ́lì, àti lójú gbogbo ilé Béńjámíní.

20. Ábínérì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dáfídì sì se àsè fún Ábínérì àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.

21. Ábínérì sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ọba Olúwa mi, wọn ó sì báa ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dáfídì sì rán Ábínérì lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.

22. Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógún púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Ábínérì kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébírónì; nítorí tí òun ti rán an lọ: òun sì ti lọ ní Àlàáfíà.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 3