Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 3:11-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Òun kò sì lè dá Ábínérì lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12. Ábínérì sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dáfídì nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Ísírẹ́lì tọ̀ ọ́ wá.”

13. Òun sì wí pé, “Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”

14. Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ sí Iṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù pé, “Fi Míkálì obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rún atoro àwọn Fílístínì fẹ́.”

15. Íṣíbóṣétì sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Fálítíélì ọmọ Láíṣì.

16. Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sunkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Báhúrímù Ábínérì sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.

17. Ábínérì sì bá àwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dáfídì ní ìgbà àtijọ́, láti jọba lórí yín.

18. Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì pé, ‘Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn.’ ”

19. Ábínérì sì sọ̀rọ̀ létí Béńjámẹ́nì: Ábínérì sì lọ sọ létí Dáfídì ní Hébírónì, gbogbo èyí tí ó dára lójú Ísírẹ́lì, àti lójú gbogbo ilé Béńjámíní.

20. Ábínérì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dáfídì sì se àsè fún Ábínérì àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.

21. Ábínérì sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ọba Olúwa mi, wọn ó sì báa ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dáfídì sì rán Ábínérì lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.

22. Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógún púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Ábínérì kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébírónì; nítorí tí òun ti rán an lọ: òun sì ti lọ ní Àlàáfíà.

23. Nígbà tí Jóábù àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Jóábù pé Ábínérì, ọmọ Nérì ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.

24. Jóábù sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Ábínérì tọ̀ ọ́ wá; èé ha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ.

25. Ìwọ mọ Ábínérì ọmọ Nérì, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”

26. Nígbà tí Jóábù sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Ábínérì, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sírà: Dáfídì kò sì mọ̀.

27. Ábínérì sì padà sí Hébírónì, Jóabù sì bá a tẹ̀ láàrin ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhẹ́lì arákùnrin rẹ̀.

28. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Ábínérì ọmọ Nérì:

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 3