Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ogun náà sì pẹ́ títí láàrin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì: agbára Dáfídì sì ń pọ̀ si i, ṣùgbọ́n ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ń rẹ̀yìn si i.

2. Dáfídì sì bí ọmọkùnrin ní Hébírónì: Ámónì ni àkọ́bí rẹ̀ tí Áhínóámù ará Jésírẹ́lì bí fún un.

3. Èkéjì rẹ̀ sì ni Kíléábù, tí Ábígáílì àya Nábálì ará Kárímẹ́lì;bí fún un ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ tí Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Gésúrì bí fún un.

4. Ẹ̀kẹ́rin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì;àti ìkarún ni Séfátíà ọmọ Ábítalì;

5. Ẹ̀kẹfà sì ni Ítíréámù, tí Égílà àya Dáfídì bí fún un.Wọ̀nyí ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì.

6. Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàárin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì, Ábínérì sì dì alágbára ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù.

7. Ṣọ́ọ̀lù ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rísípà, ọmọbínrin Áíyà: Íṣíbóṣétì sì bi Ábínérì léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”

8. Ábínérì sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣibósẹ́tì sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Júdà bí? Di òní yìí ni mọ ṣàáánú fún ìdílé Ṣọ́ọ̀lù bàbá rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lóní?

9. Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Ábínérì, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dáfídì, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 3