Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 23:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára tí Dáfídì ní:Jósébù-básébè ti ará Takímónì ni olorí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.

9. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Élíásárì ọmọ Dódò ará Áhóhì, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti wà pẹ̀lú Dáfídì, nígbà tí wọ́n pe àwọn Fílístínì ní ìjà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì ti lọ kúrò.

10. Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Fílístínì títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.

11. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Sámímà ọmọ Ágè ará Hárárì, àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ ní Léhì, oko kan tí ó kún fun ẹwẹ: àwọn ènìyàn sì sá kúrò níwájú àwọn Fílístínì.

12. Òun sì dúró láàrin méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbàá sílẹ̀, ó sì pa àwọn Fílístínì Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá.

13. Àwọn mẹ́ta nínú ọgbọ̀n olórí sì sọkalẹ̀, wọ́n sì tọ Dáfídì wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Ádúlámù: ọ̀wọ́ àwọn Fílístínì sì dó sí àfonífojì Réfáímù.

14. Dáfídì sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Fílístínì sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà náà.

15. Dáfídì sì ń pòùngbẹ, ó wí bayìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kàǹga tí ń bẹ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu bodè.”

16. Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Fílístínì lọ, wọ́n sì fa omi látinú kàǹga Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu bodè, wọ́n sì mú tọ Dáfídì wá: òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa.

17. Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un.Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe.

18. Ábíṣáì, arákùnrin Jóábù, ọmọ Sérúíà, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

19. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: ó sì jẹ́ olórí fún wọn: ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.

20. Bénáyà, ọmọ Jéhóíádà, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabiseélì, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Áríélì méjì ti Móábù; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjòdídì.

21. Ó sì pa ará Éjíbítì kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Éjíbítì náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n òun sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Éjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.

22. Nǹkan wọ̀nyí ní Banáyà ọmọ Jéhóíádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 23