Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 23:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,òwúrọ̀ tí kò ní ìkúukùu,nígbà tí koríko tútùbá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

5. “Lóòtọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run,ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,tí a túnṣe nínú ohun gbogbo,tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi,ilé mi kò lè ṣe kí ó má dágbà.

6. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Bélíálì yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣátì,nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.

7. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóòfi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká;wọn ó Jóná lúúlú níbì kan náà.”

8. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára tí Dáfídì ní:Jósébù-básébè ti ará Takímónì ni olorí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 23