Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 23:19-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: ó sì jẹ́ olórí fún wọn: ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.

20. Bénáyà, ọmọ Jéhóíádà, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabiseélì, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Áríélì méjì ti Móábù; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjòdídì.

21. Ó sì pa ará Éjíbítì kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Éjíbítì náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n òun sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Éjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.

22. Nǹkan wọ̀nyí ní Banáyà ọmọ Jéhóíádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.

23. Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dáfídì sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.

24. Ásáhélì arákùnrin Jóábù sì Jásí ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà;Élíhánánì ọmọ Dódò ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù;

25. Ṣámà ará Háródì,Élíkà ará Háródì.

26. Hélésì ará Pálitì,Irá ọmọ Íkéṣì ará Tékóà;

27. Ábíésérì ará Ánétótì,Móbúnnáì Húṣátítì;

28. Sálímónì ará Áhóhì,Máháráì ará Nétófà;

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 23