Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 23:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì.“Dáfídì ọmọ Jésè,àní ọkùnrin tí a ti gbéga,ẹni-àmì òróró Ọlọ́run Jákọ́bù,àti olórin dídùn Ísírẹ́lì wí pé:

2. “Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.

3. Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni,àpáta Ísírélì sọ fún mi pé:‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo,tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

4. Yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,òwúrọ̀ tí kò ní ìkúukùu,nígbà tí koríko tútùbá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

5. “Lóòtọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run,ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,tí a túnṣe nínú ohun gbogbo,tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi,ilé mi kò lè ṣe kí ó má dágbà.

6. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Bélíálì yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣátì,nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 23