Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:5-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

6. Ọ̀já isà-òkú yí mi káàkiri;ìkẹ́kùn ikú dojú kọ mí.

7. Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.Ó sí gbóhùn mi láti tẹ́ḿpìlì rẹ̀igbe mí wọ etí rẹ̀.

8. “Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,ó sì mì, nítorí tí ó bínú.

9. Èéfín sì jáde láti ihò-imú rẹ̀ wá;iná láti ẹnu rẹ̀ wá,ó sì ń jónirun, ẹ̀yín sì ń ràn nípasẹ rẹ̀.

10. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

11. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

12. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,àní ìsúdudu ìkùukùu àwọ̀n sánmà.

13. Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ẹ̀yín-iná ràn.

14. Olúwa sán ààrá láti ọ̀run wá,ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.

15. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.

16. Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.

17. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.

18. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19. Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi:ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀hìntì mi.

20. Ó sì mú mi wá sí àyè ńlá:ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22