Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:49-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi.Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.

50. Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,láàrin àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.

51. Òun ni ilé-ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;ó sì fi àánú hàn fún ẹni-àmì-òróró rẹ̀,fún Dáfídì, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22