Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:45-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi;bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi.

46. Àyà yóò pá àwọn àlejò,wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.

47. “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.

48. Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.

49. Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi.Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.

50. Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,láàrin àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.

51. Òun ni ilé-ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;ó sì fi àánú hàn fún ẹni-àmì-òróró rẹ̀,fún Dáfídì, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22