Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:23-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.

24. Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í,èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.

25. Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà-mímọ́ mi níwájú rẹ̀.

26. “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú,àti fún ẹni-ìdúró-ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró-ṣinṣin ní òdodo.

27. Fún onínú-funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;àti fún ẹni-wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.

28. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

29. Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

30. Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárin ogun kọjá;nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.

31. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò.Òun sì niaṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

32. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.

33. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.

34. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22