Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

11. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

12. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,àní ìsúdudu ìkùukùu àwọ̀n sánmà.

13. Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ẹ̀yín-iná ràn.

14. Olúwa sán ààrá láti ọ̀run wá,ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.

15. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.

16. Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.

17. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.

18. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19. Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi:ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀hìntì mi.

20. Ó sì mú mi wá sí àyè ńlá:ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.

21. “Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.

22. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́,èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

23. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.

24. Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í,èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22