Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 2:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Dáfídì sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hébúrónì àti ìlú rẹ̀ mìíràn.

4. Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Júdà wá sí Hébúrónì, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Júdà.Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì pé, àwọn ọkùnrin ti Jábésì Gílíádì ni ó sin òkú Ṣọ́ọ̀lù,

5. Ó rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jábésì Gílíádì láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Ṣọ́ọ̀lù ọ̀gá yín nípa sí sin ín.

6. Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí.

7. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Ṣọ́ọ̀lù ọba yín ti kú, ilé Júdà sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”

8. Lákòókò yìí, Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ṣọ́ọ̀lù ti mú Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì mú un kọjá sí Máhánáímù.

9. Ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì Áṣúrì àti Jésérẹ́lì àti lórí Éfúráímù àti lórí Bẹ́ńjámínì àti lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

10. Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba fún ọdún méjì. Ilé Júdà sì ń tọ Dáfídì lẹ́yìn.

11. Gbogbo àkókò tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 2