Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn àkókò yìí, Dáfídì wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.”Dáfídì sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dáa lóhùn pé, “Sí Hébúrónì.”

2. Nígbà náà ni Dáfídì gòkè lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Áhínóámù ará Jésérẹ́lì, àti Ábígáílì obìnrin opó Nábálì ti Kámẹ́lì.

3. Dáfídì sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hébúrónì àti ìlú rẹ̀ mìíràn.

4. Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Júdà wá sí Hébúrónì, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Júdà.Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì pé, àwọn ọkùnrin ti Jábésì Gílíádì ni ó sin òkú Ṣọ́ọ̀lù,

5. Ó rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jábésì Gílíádì láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Ṣọ́ọ̀lù ọ̀gá yín nípa sí sin ín.

6. Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 2