Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 16:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.”

20. Ábúsálómù sì wí fún Áhítófélì pé, “Ẹ bá ará yín gbímọ ohun tí àwa ó ṣe.”

21. Áhítófélì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni-ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọdọ rẹ yóò sì le.”

22. Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Ábúsálómù ní òrùlé; Ábúsálómù sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Ísírẹ́lì.

23. Ìmọ̀ Áhítófélì tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Áhítófélì fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù sì rí.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 16