Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 16:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ̀njú mi, Olúwa yóò sì fi ire san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”

13. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.

14. Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jódánì, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.

15. Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wá sí Jérúsálẹ́mù, Áhítófélì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

16. Ó sì ṣe, nígbà tí Húṣáì ará Áríkì, ọ̀rẹ́ Dáfídì tọ Ábúsálómù wá, Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”

17. Ábúsálómù sì wí fún Húṣáì pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?”

18. Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí Olúwa, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó.

19. Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.”

20. Ábúsálómù sì wí fún Áhítófélì pé, “Ẹ bá ará yín gbímọ ohun tí àwa ó ṣe.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 16