Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 16:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Dáfídì sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣíbà ìránṣẹ́ Mefíbóṣétì sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún ṣírì àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn ún èṣo ẹ̀rún, àti ìgò ọtí-wáìnì kan.

2. Ọba sì wí fún Ṣíbà pé, “Kí ni wọ̀nyí?”Ṣíbà sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọdọmọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí-wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”

3. Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?”Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jérúsálẹ́mù; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Ísírẹ́lì yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”

4. Ọba sì wí fún Síbà pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefíbóṣétì jẹ́ tìrẹ.”Ṣíbà sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí ore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, Olúwa mi ọba.”

5. Dáfídì ọba sì dé Bahúrímù, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Ṣọ́ọ̀lù wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣíméhì, ọmọ Gérà: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀.

6. Ó sì sọ òkúta sí Dáfídì, àti sí gbogbo àwọn ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀.

7. Báyìí ni Ṣímé sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Bélíálì.

8. Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Ṣọ́ọ̀lù padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jọba; Olúwa ti fi ijọba náà lé Ábúsálómù ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”

9. Ábíṣáì ọmọ Serúià sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú Olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”

10. Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yín ọmọ́ Séríià? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé: ‘Bú Dáfídì!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

11. Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Bẹ́ńjámínì yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un.

12. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ̀njú mi, Olúwa yóò sì fi ire san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”

13. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 16