Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:32-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí Olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.

33. Ǹjẹ́ kí Olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

34. Ábúsálómù sì sá.Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si ríi pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ̀nà lẹ́yin rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”

35. Jónádábù sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”

36. Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sòkè, wọ́n sì sunkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.

37. Ábúsálómù sì sá, ó sì tọ Támáì lọ, ọmọ Ámíhúdù, ọba Gésúrì. Dáfídì sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lojojúmọ́.

38. Ábúsálómù sì sá, ó sì lọ sí Géṣúrì ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta.

39. Ọkàn Dáfídì ọba sì fà gidigidi sí Ábúsálómù: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Ámúnónì: ó sáà ti kú.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13