Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

30. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìhìn sì dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé, “Ábúsálómù pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.”

31. Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.

32. Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí Olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.

33. Ǹjẹ́ kí Olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

34. Ábúsálómù sì sá.Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si ríi pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ̀nà lẹ́yin rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”

35. Jónádábù sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13