Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ọba sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má báà mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.

26. Ábúsálómù sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Ámúnónì ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”

27. Ábúsálómù sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Ámúnónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.

28. Ábúsálómù sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsí àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Ámúnónì dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Ámúnónì,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.”

29. Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

30. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìhìn sì dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé, “Ábúsálómù pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.”

31. Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.

32. Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí Olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.

33. Ǹjẹ́ kí Olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13