Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ámúnónì sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúndíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Ámúnónì láti bá a dàpọ̀.

3. Ṣùgbọ́n Ámúnónì ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jónádábù, ọmọ Ṣíméà ẹ̀gbọ́n Dáfídì: Jónádábù sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi.

4. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”Ámúnónì sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Támárì àbúrò Ábúsálómù arákùnrin mi.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13