Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.

13. Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.”

14. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.

15. Ámúnónì sì kóríra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Ámúnónì sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”

16. Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.”Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀.

17. Òun sì pe ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.”

18. Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan làra rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúndíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.

19. Támárì sì bu èérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.

20. Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Támárì sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13