Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Támárì; Ámúnónì ọmọ Dáfídì sì fẹ́ràn rẹ̀.

2. Ámúnónì sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúndíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Ámúnónì láti bá a dàpọ̀.

3. Ṣùgbọ́n Ámúnónì ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jónádábù, ọmọ Ṣíméà ẹ̀gbọ́n Dáfídì: Jónádábù sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi.

4. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”Ámúnónì sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Támárì àbúrò Ábúsálómù arákùnrin mi.”

5. Jónádábù sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ó, ìwọ ó sì wá fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Támárì àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ́ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”

6. Ámúnónì sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Ámúnónì sì wí fún ọba pé, “Jọ́wọ́, jẹ́ kí Támárì àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”

7. Dáfídì sì ránṣẹ́ sí Támárì ní ilé pé, “Lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì ṣe òunjẹ́ fún un.”

8. Támárì sì lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdúbúlẹ̀. Támárì sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.

9. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.Ámúnónì sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 13