Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 12:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Jóábù sì bá Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn.

27. Jóábù sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rábà jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olomi.

28. Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi.”

29. Dáfídì sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 12