Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 12:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì rán Nátanì sí Dáfídì òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ talákà.

2. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀.

3. Ṣùgbọ́n ọkùnrin talákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dúbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.

4. “Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀: láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá: o sì mú àgùntàn ọkùnrin talákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”

5. Ìbínú Dáfídì sì fàru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Nátanì pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkán yìí, kíkú ni yóò kú.

6. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rinmẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”

7. Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi fi ọ́ jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù.

8. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ.

9. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 12