Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 11:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹṣẹ̀ rẹ.” Ùráyà sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

9. Ṣùgbọ́n Ùráyà sun l'ẹ́nu ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.

10. Nígbà tí wọ́n sì sọ fún Dáfídì pé, “Ùráyà kò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀,” Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, “Ṣebí ọ̀nà àjò ni ìwọ ti wá? Èé ha ti ṣe tí ìwọ kò fi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ.”

11. Ùráyà sì wí fún Dáfídì pé, “Àpótí-ẹ̀rí, àti Ísírẹ́lì, àti Júdà jókòó nínú àgọ́; àti Jóábù olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá: èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ ati lati mu, àti láti bá obìnrin mi sùn? Bí ìwọ bá wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láàyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí.”

12. Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, “Ṣì dúró níhìn ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ.” Ùráyà sì dúró ní Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ náà, àti ijọ́ kejì.

13. Dáfídì sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ́ lọ sí ilé rẹ̀.

14. Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dáfídì sì kọ̀wé sí Jóábù, ó fi rán Ùráyà.

15. Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Ùráyà ṣíwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fà sẹ́yìn, kí wọn lè kọ lù ú, kí ó sì kú.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 11