Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 9:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jéhù ọmọ Jéhóṣáfátì, ọmọ Mímísì kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ.

3. Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ Nígbà náà, sí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!”

4. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti-Gílíádì.

5. Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí.“Fún èwo nínú wa?” Jéhù béèrè.“Fún ọ, Alákóso,” Ó dáhùn.

6. Jéhù dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jéhù; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Ísírẹ́lì.

7. Kí ìwọ kí ó pa ilé Áhábù ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jésébélì.

8. Gbogbo ilé Áhábù yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Áhábù gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí òmìnira.

9. Èmi yóò ṣe ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí ilé Jéróbóhámù ọmọ Nábátì àti ilé Bááṣà ọmọ Áhíjà.

10. Fún Jésébélì, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jésírẹ́lì, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkúrẹ̀.’ ” Nígbà náà ó sí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.

11. Nígbà tí Jéhù jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?”Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jéhù fèsì.

12. “Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Ṣọ fún wa.”Jéhù wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ ”

13. Wọ́n ṣe gírì, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní órí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ipè, wọ́n sì kígbe, “Jéhù jẹ ọba!”

Ka pipe ipin 2 Ọba 9