Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 9:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wòlíì Èlíṣà fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, “Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti-Gílíádì.

2. Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jéhù ọmọ Jéhóṣáfátì, ọmọ Mímísì kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ.

3. Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ Nígbà náà, sí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!”

4. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti-Gílíádì.

5. Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí.“Fún èwo nínú wa?” Jéhù béèrè.“Fún ọ, Alákóso,” Ó dáhùn.

6. Jéhù dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jéhù; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Ísírẹ́lì.

7. Kí ìwọ kí ó pa ilé Áhábù ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jésébélì.

8. Gbogbo ilé Áhábù yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Áhábù gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí òmìnira.

9. Èmi yóò ṣe ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí ilé Jéróbóhámù ọmọ Nábátì àti ilé Bááṣà ọmọ Áhíjà.

10. Fún Jésébélì, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jésírẹ́lì, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkúrẹ̀.’ ” Nígbà náà ó sí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.

11. Nígbà tí Jéhù jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?”Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jéhù fèsì.

12. “Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Ṣọ fún wa.”Jéhù wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ ”

13. Wọ́n ṣe gírì, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní órí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ipè, wọ́n sì kígbe, “Jéhù jẹ ọba!”

14. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù ọmọ Jéhósáfátì, ọmọ Nímsì, dìtẹ̀ sí Jórámù. (Nísinsìnyí Jórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì ti ń dábòbò Ramoti-Gílíádì nítorí Hásáélì ọba Árámù:

15. Ṣùgbọ́n ọba Jórámù ti padà sí Jéṣérẹ́lì láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Árámù ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hásáélì ti Árámù). Jéhù wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jéṣérẹ́lì.”

16. Nígbà náà ó wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jésérẹ́lì, nítorí Jórámù ń sinmi níbẹ̀ àti ọba Áhásáyà tilọ láti lọ wò ó.

17. Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Jórámù pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

18. Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jéhù ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jéhù sì dáhùn. “Ṣubú sími lẹ́yìn.”Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 9