Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 3:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti ìyá àti bàbá rẹ̀ ti ṣe. Ó gbé òkúta ère ti Báálì tí baba rẹ̀ ti ṣe.

3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ti fi Ísírẹ́lì bú láti dẹ́ṣẹ̀; kò sì yí kúrò lọ́dọ̀ wọn.

4. Nísinsìn yìí Mésà ọba Móábù ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọgọ́rún ẹgbẹ̀rùnún ọ̀dọ́ àgùntàn àti pẹ̀lú irú ọgọ́runún ẹgbẹ̀rúnún (hundred thousand) àgbò.

5. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Áhábù, ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Ísírẹ́lì.

6. Lásìkò ìgbà yìí ọba Jéhórámù jáde kúrò ní Ṣamáríà ó sì yí gbogbo Ísírẹ́lì nípò padà.

7. Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jéhóṣáfátì ọba Júdà: “Ọba Móábù sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Móábù jà?”“Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ,” Ó dáhùn. “Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

8. “Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dójukọ wọ́n?” Ó bèèrè,“Lọ́nà ihà Ékírónì,” ó dáhùn.

9. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Isírẹ́lì jáde lọ pẹ̀lú ọba Júdà àti ọba Édómù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.

10. “Kí ni?” Ọba Ísírẹ́lì kígbe sókè. “Ṣé Olúwa pè àwa ọba mẹ́tẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́?”

11. Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì sì wí pé, “Ṣé kò sí wòlíì Olúwa níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì wà níbí. Ó máa ṣábà bu omi sí ọwọ́ Èlíjàh.”

12. Jèhóṣáfátì wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ.

13. Èlíṣà wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì bàbá rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.”“Rárá,” ọba Ísírẹ́lì dá a lóhùn, “nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́.”

14. Èlíṣà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jèhósáfátì ọba Júdà, Èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ.

15. Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí mú wá fún mi ohun èlò orin olókun.”Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Èlíṣà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 3