Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 3:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jéhórámù ọmọ Áhábù ó sì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ní ọdún kejìdínlógún ti Jéhósáfátì ọba Júdà, ó sì jọba fún ọdún méjìlá.

2. Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti ìyá àti bàbá rẹ̀ ti ṣe. Ó gbé òkúta ère ti Báálì tí baba rẹ̀ ti ṣe.

3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ti fi Ísírẹ́lì bú láti dẹ́ṣẹ̀; kò sì yí kúrò lọ́dọ̀ wọn.

4. Nísinsìn yìí Mésà ọba Móábù ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọgọ́rún ẹgbẹ̀rùnún ọ̀dọ́ àgùntàn àti pẹ̀lú irú ọgọ́runún ẹgbẹ̀rúnún (hundred thousand) àgbò.

5. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Áhábù, ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Ísírẹ́lì.

6. Lásìkò ìgbà yìí ọba Jéhórámù jáde kúrò ní Ṣamáríà ó sì yí gbogbo Ísírẹ́lì nípò padà.

7. Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jéhóṣáfátì ọba Júdà: “Ọba Móábù sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Móábù jà?”“Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ,” Ó dáhùn. “Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

8. “Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dójukọ wọ́n?” Ó bèèrè,“Lọ́nà ihà Ékírónì,” ó dáhùn.

Ka pipe ipin 2 Ọba 3