Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:24-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.

25. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

26. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì

27. Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.

28. Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.

29. Ní ìgbà Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tígílátì Pílésérì ọba Ásíríà wá, ó sì mú Íjónì, Abeli-Bẹti-Máákà, Jánóà, Kédéṣì àti Hásórì. Ó gba Gíléádì àti Gálílì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náftalì. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Ásíríyà.

30. Nígbà náà, Hóséà ọmọ Álíyà, dìtẹ̀ sí Pékà ọmọ Remalíyà. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jótamù ọmọ Ùsáyà.

31. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Pékà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

32. Ní ọdún keje Pékà ọmọ Remalíà ọba Ísírẹ́lì, Jótamù ọmọ Ùsáyà ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

33. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jérúṣà ọmọbìnrin Ṣádókù.

34. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí bàbá a rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe.

35. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jótamù tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

36. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jótamù, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

37. (Ní ayé ìgbà a nì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Résínì ọba Ṣíríà àti Pékà ọmọ Remálíà láti dojúkọ Júdà).

38. Jótamù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Áhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15