Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:22-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pékáhíà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

23. Ní ọdún kẹẹ̀dógún Ásáríyà ọba Júdà, Pékáhíà ọmọ Ménáhémù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọdún méjì.

24. Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.

25. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

26. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì

27. Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.

28. Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.

29. Ní ìgbà Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tígílátì Pílésérì ọba Ásíríà wá, ó sì mú Íjónì, Abeli-Bẹti-Máákà, Jánóà, Kédéṣì àti Hásórì. Ó gba Gíléádì àti Gálílì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náftalì. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Ásíríyà.

30. Nígbà náà, Hóséà ọmọ Álíyà, dìtẹ̀ sí Pékà ọmọ Remalíyà. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jótamù ọmọ Ùsáyà.

31. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Pékà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

32. Ní ọdún keje Pékà ọmọ Remalíà ọba Ísírẹ́lì, Jótamù ọmọ Ùsáyà ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

33. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jérúṣà ọmọbìnrin Ṣádókù.

34. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí bàbá a rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe.

35. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jótamù tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

36. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jótamù, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

37. (Ní ayé ìgbà a nì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Résínì ọba Ṣíríà àti Pékà ọmọ Remálíà láti dojúkọ Júdà).

Ka pipe ipin 2 Ọba 15