Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásáríyà ọmọ Ámásáyà ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

2. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógún nígbà tí o di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a má a jẹ́ Jékólíà; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ámásáyà ti ṣe.

4. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn náà tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

5. Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jótamì, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

6. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ásáríyà, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15