Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 9:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. A sì mú àwọn ẹsin Sólómónì láti ilẹ̀ òkèrè láti Éjíbítì àti láti gbogbo ìlú

29. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Sólómónì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Nátanì wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà ará Sílónì àti nínú ìran Ídò, wòlíì tí o kan Jéróbámù ọmọ Nébátì?

30. Sólómónì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún (40)

31. Sólómónì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀, Réhóbóámù, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 9