Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 9:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó. Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá.

22. Ọba Solómónì sì tóbi nínú ọlá ńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.

23. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojú rere lọ́dọ̀ Sólómónì láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

24. Ní ọdọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹsin àti ìbaka wá.

25. Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàfà àwọn ẹsin (12,000), tí ó ba mọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jérúsálẹ́mù.

26. Ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò títí dé ilé àwọn ará fìlístínì àti títí ó fi dé agbègbè ti Éjíbítì.

27. Ọba sì ṣe fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọpọ̀ ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí òkúta àti igi kédárì ó sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí igi síkámórè ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ gígi.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 9