Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 9:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solómónì ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò agbo ilé ní ibi igbó Lébánonì ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì sí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.

21. Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Húrámù ń bojútó. Ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin, àti ìnàkí àti ẹyẹ ológe wá.

22. Ọba Solómónì sì tóbi nínú ọlá ńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.

23. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojú rere lọ́dọ̀ Sólómónì láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

24. Ní ọdọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹsin àti ìbaka wá.

25. Sólómónì sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàfà àwọn ẹsin (12,000), tí ó ba mọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jérúsálẹ́mù.

26. Ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò títí dé ilé àwọn ará fìlístínì àti títí ó fi dé agbègbè ti Éjíbítì.

27. Ọba sì ṣe fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọpọ̀ ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí òkúta àti igi kédárì ó sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí igi síkámórè ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ gígi.

28. A sì mú àwọn ẹsin Sólómónì láti ilẹ̀ òkèrè láti Éjíbítì àti láti gbogbo ìlú

29. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Sólómónì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Nátanì wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà ará Sílónì àti nínú ìran Ídò, wòlíì tí o kan Jéróbámù ọmọ Nébátì?

30. Sólómónì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún (40)

31. Sólómónì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀, Réhóbóámù, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 9