Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 7:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ní ọjọ́ kẹ́jọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyà símímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àṣe náà fún ọjọ́ méje sí i.

10. Ní ọjọ́ kẹtàlélógún (23rd day) tí oṣù kéje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì àti Sólómónì, àti fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

11. Nígbà tí Sólómónì ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkálárarẹ̀,

12. Olúwa sì farahàn ní òru ó sì wí pé:“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibííyí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.

13. “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma báà sí òjò, tàbí láti pàsẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-àrùn sí àárin àwọn ènìyàn mi,

14. Tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.

15. Nísisinyí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbíyìí.

16. Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.

17. “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run:

18. Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mu wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Ísírẹ́lì.

19. “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin Ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n,

20. Nígbà náà ni èmi yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin gbogbo ènìyàn,

21. Àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsinyí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí Olúwa fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’

22. Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba Ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 7