Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 4:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó ṣe àwọn kòkò pẹ̀lu, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n.Bẹ́ẹ̀ ni Húrámì parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Sólómónì ní ilé Ọlọ́run:

12. Àwọn òpó méje;àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lóri òpó méjèèje náà;àti ìṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà;

13. Ọgọ́rùn ún mẹ́rin Pomígíránátì fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹṣẹ̀ méjì Pomigiranati ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lóri àwọn òpó náà;

14. Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;

15. Agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀;

16. Àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fara pẹ́ẹ.Gbogbo ohun èlò ti Húrámí-bì fi idẹ dídán ṣe fún Sólómónì ọba, fún ilé Olúwa jẹ́ idẹ dídán.

17. Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ní àárin méjì Súkótì àti Ṣárétánì.

18. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Sólómónì ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ̀n.

19. Sólómónì pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run:pẹpẹ wúràtábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;

20. Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;

21. Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú (ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn);

22. Pẹ̀lú àlùmágàjí fìtílà, àti àwo-kòtò àti ṣíbí àti àwo-kòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹ́ḿpìlì: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn àbáwọ inú gbọ̀ngàn ńlá.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 4