Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 36:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránsẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣíwájú àti ṣíwájú síi, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìransẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ sẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run ṣe ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì sí àtúnṣe.

17. Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Bábílónì tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdé bìnrin, wúndíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadinésárì lọ́wọ́.

18. Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Bábílónì, níńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀.

19. Wọ́n sì fi iná sí ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun-èlò ibẹ̀ jẹ́.

20. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára.

21. Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremíà.

22. Ní ọdún kín-ín-ní Kírúsì ọba Pásíà, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremáyà sọ báà le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kírúsì ọba Pásíà láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

23. “Èyí ni ohun tí Kérúsì ọba Pásíà sọ wí pé:“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jérúsálẹ́mù ti Júdà. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 36