Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 34:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hílkíà àlùfáà sì rí ìwe òfin Olúwa tí a ti fi fún-un láti ọwọ́ Mósè.

15. Hílíkíyà sì wí fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwe òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣáfánì.

16. Nígbà náà Ṣáfánì sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún-un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́.

17. Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìsẹ́.”

18. Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣáfánì sì kà níwájú ọba.

19. Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 34