Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 30:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù,

19. Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

20. Olúwa sì gbọ́ ti Hesékíà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.

21. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

22. Heṣekáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àṣè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

23. Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́.

24. Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn: Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.

25. Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jérúsálẹ́mù: nítorí láti ọjọ́ Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, irú èyí kò sí ní Jérúsálẹ́mù.

27. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àni sí ọ̀run.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 30