Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 30:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: wọn pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.

18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù,

19. Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

20. Olúwa sì gbọ́ ti Hesékíà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.

21. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

22. Heṣekáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àṣè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

23. Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́.

24. Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn: Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.

25. Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jérúsálẹ́mù: nítorí láti ọjọ́ Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, irú èyí kò sí ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 30