Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 24:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.

20. Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Ṣákáríhà ọmọ Jéhóíádà wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21. Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa

22. Ọba Jóáṣì kò rántí inú rere tí Jéhóiádà baba Ṣakaráyà ti fi hàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣírò.”

23. Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ ogun Árámì yàn láti dojúkọ Jóáṣì; wọ́n gbógun ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa gbogbo àwọn asáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Dámásíkọ́sì.

24. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ogun Árámì ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Jóásì.

25. Nígbà tí àwọn ará Árámù kúrò, wọ́n fi Jóásì sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn onísẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jéhóiádà àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba.

26. Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ Ṣábádì, ọmọ Ṣíméátì arábìnrin Ámónì àti Jóhéṣábádì ọmọ Ṣímírítì arábìnrin Móábì.

27. Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ lọ́pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwe ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 24