Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 21:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà Jéhóṣáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì. Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2. Àwọn ará kùnrin Jéhóramù ọmọ Jéhóṣáfatì jẹ́ Áṣáríyà, Jèhíeli, Ṣekárià. Ásáríyàhù, Míkáélí àti Ṣefátíá. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jéhóṣafátì ọba Ìsírẹlì.

3. Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bun púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Júdà, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jéhóramù nítori òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.

4. Nígbà tí Jéhórámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó pa gbogbo àwọn arákùrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìrin ọba Ìsirẹ́lì.

5. Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjọ.

6. Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìrin Áhábù. Ó ṣe búburú lójú Olúwa.

7. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dáfídì kì í ṣe ífẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dáfídì run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.

8. Ní àkókò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀.

9. Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhórámù lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Édómù yí i ká àti àwọn alákóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì sẹ́gun wọn ní òru.

10. Títí di ọjọ́ òní ni Édómù ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Júdà.Líbínà ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jéhórámì ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀.

11. Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Júdà. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ó se àgbérè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.

12. Jóhórámì gba ìwé láti ọwọ́ Èlíjà wòlíì, tí ó wí pé:“Èyí ní ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba à rẹ Dáfídì wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jèhóṣáfátì tàbí Ásà ọba Júdà.

13. Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ìwọ sì ti tọ́ Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé bàbá à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ.

14. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ́ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn ńlá.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 21