Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 20:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Édómù wá láti gbé ogun tọ Jéhóṣáfátì wá.

2. Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jéhóṣáfátì, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Édómù, láti apákejì òkun. Ó ti wà ní Hásásónì Támárì náà” (èyí ni wí pé, Énígédì).

3. Ní ìdágìrì, Jéhóṣáfátì pinnú láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde ààwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Júdà.

4. Àwọn ènìyàn Júdà sì kó ara wọn jọpọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Júdà láti wá a.

5. Nígbà náà Jéhóṣáfátì dìde dúró níwájú àpèjọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.

6. O sì wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.

7. Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣé o kò lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwajú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí o sì fi fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?

8. Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé,

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 20