Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 15:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlu kan sí òmíràn nítorí Olúwa ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.

7. Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì se sú ọ. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ”

8. Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù. Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé Olúwa

9. Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀

10. Wọ́n péjọ sí Jérúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀dógún ti ìjọba Ásà.

11. Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí Olúwa ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà.

12. Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.

13. Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 15