Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 10:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi fi pàṣán nà yín pẹ̀lú ẹgba: Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ”

12. Ní ọjọ́ kẹ̀ta Jéróbóámù àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹ̀ta.”

13. Ọba sì dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Ó kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbààgbà,

14. Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèé.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì tẹ́tísi àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì nípasẹ̀ Áhíjà ará Ṣilò.

16. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé:“Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì,ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè?Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì!”Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn.

17. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní ìlú Júdà, Réhóbóámù pàpà ń jọba lórí wọn.

18. Ọba Réhóbóámù rán Ádónírámù jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúuru, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Réhóbóámù bí ó tí wù kí ó rí, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jérúsálẹ́mù.

19. Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì sì wà ní ìsọ̀tẹ̀ lórí ilé Dáfídì títí fi di òní yìí.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 10