Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 7:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tú jáde láti Mísípà. Wọ́n sì ń lépa àwọn Fílístínì, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Bẹti-Káírì.

12. Sámúẹ́lì mú òkúta kan ó sì fi lé lẹ̀ láàárin Mísípà àti Ṣénì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbẹnésérì, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Fílístínì, wọn kò sì wá sí agbégbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́.Ní gbogbo ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Fílístínì.

14. Àwọn ìlú láti Ékírónì dé Gátì tí àwọn Fílístínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti gbà padà fún Ísírẹ́lì, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Fílístínì. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàárin Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.

15. Sámúẹ́lì tẹ̀ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Ísírẹ́lì. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀.

16. Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Bẹ́tẹ́lì dé Gílígálì dé Mísípà, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ibi wọ̀nyí.

17. Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rámà, níbí, ó sì tún ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 7