Kẹ̀kẹ̀ ẹrù wá sí pápá Jóṣúà ti Bẹti-Sémésì, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rúbọ sísun sí Olúwa.